Isaiah 5:28
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àwọn ọfà wọn múná, gbogbo ọrun wọn sì le; pátákò àwọn ẹṣin wọn le bí òkúta akọ, àwọn àgbá kẹ̀kẹ́ wọn sì dàbí ìjì líle.
Isaiah 5:28 in English
Isaiah 5:28 · Berean Standard Bible
Their arrows are sharpened, and all their bows are strung. The hooves of their horses are like flint; their chariot wheels are like a whirlwind.
Context
26Yóò sì gbé ọ̀págun sókè sí àwọn orílẹ̀-èdè tí ó jìnnà,
yóò sì kọ sí wọn tí ó wà ní ìpẹ̀kun ilẹ̀.
Sì kíyèsi, wọ́n yóò yára wá kánkán. 27Kò sí ẹni tí yóò rẹ̀ nínú wọn, tàbí tí yóò kọsẹ̀,
kò sí ẹni tí yóò tòògbé tàbí tí yóò sùn;
bẹ́ẹ̀ ni àmùrè ẹ̀gbẹ́ wọn kì yóò tú,
bẹ́ẹ̀ ni okùn sálúbàtà wọn kì yóò ja. 28Àwọn ọfà wọn múná,
gbogbo ọrun wọn sì le;
pátákò àwọn ẹṣin wọn le bí òkúta akọ,
àwọn àgbá kẹ̀kẹ́ wọn sì dàbí ìjì líle. 29Bíbú wọn dàbí tí kìnnìún,
wọ́n bú bí ẹgbọrọ kìnnìún,
wọ́n ń kọ bí wọ́n ti di ẹran ọdẹ wọn mú
tí wọn sì gbé e lọ láìsí ẹni tí yóò gbà á là. 30Ní ọjọ́ náà, wọn yóò hó lé e lórí
gẹ́gẹ́ bí i rírú omi Òkun.
Bí ènìyàn bá sì wo ilẹ̀,
yóò rí òkùnkùn àti ìbànújẹ́;
pẹ̀lúpẹ̀lú ìmọ́lẹ̀ yóò di òkùnkùn pẹ̀lú kurukuru rẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.