Isaiah 5:30
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ní ọjọ́ náà, wọn yóò hó lé e lórí gẹ́gẹ́ bí i rírú omi Òkun. Bí ènìyàn bá sì wo ilẹ̀, yóò rí òkùnkùn àti ìbànújẹ́; pẹ̀lúpẹ̀lú ìmọ́lẹ̀ yóò di òkùnkùn pẹ̀lú kurukuru rẹ̀.
Isaiah 5:30 in English
Isaiah 5:30 · Berean Standard Bible
In that day they will roar over it, like the roaring of the sea. If one looks over the land, he will see darkness and distress; even the light will be obscured by clouds.
Context
28Àwọn ọfà wọn múná,
gbogbo ọrun wọn sì le;
pátákò àwọn ẹṣin wọn le bí òkúta akọ,
àwọn àgbá kẹ̀kẹ́ wọn sì dàbí ìjì líle. 29Bíbú wọn dàbí tí kìnnìún,
wọ́n bú bí ẹgbọrọ kìnnìún,
wọ́n ń kọ bí wọ́n ti di ẹran ọdẹ wọn mú
tí wọn sì gbé e lọ láìsí ẹni tí yóò gbà á là. 30Ní ọjọ́ náà, wọn yóò hó lé e lórí
gẹ́gẹ́ bí i rírú omi Òkun.
Bí ènìyàn bá sì wo ilẹ̀,
yóò rí òkùnkùn àti ìbànújẹ́;
pẹ̀lúpẹ̀lú ìmọ́lẹ̀ yóò di òkùnkùn pẹ̀lú kurukuru rẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.