Isaiah 5:26
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Yóò sì gbé ọ̀págun sókè sí àwọn orílẹ̀-èdè tí ó jìnnà, yóò sì kọ sí wọn tí ó wà ní ìpẹ̀kun ilẹ̀. Sì kíyèsi, wọ́n yóò yára wá kánkán.
Isaiah 5:26 in English
Isaiah 5:26 · Berean Standard Bible
He lifts a banner for the distant nations and whistles for those at the ends of the earth. Behold—how speedily and swiftly they come!
Context
24Nítorí náà, gẹ́gẹ́ bí ahọ́n iná ṣe ń jó àgékù koríko run
àti bí koríko ṣe rẹlẹ̀ wẹ̀sì nínú iná,
bẹ́ẹ̀ ni egbò wọn yóò jẹrà
tí òdodo wọn yóò sì fẹ́ lọ bí eruku:
nítorí pé wọ́n ti kọ òfin Olúwa àwọn ọmọ-ogun sílẹ̀
wọ́n sì gan ọ̀rọ̀ Ẹni mímọ́ Israẹli. 25Nítorí náà, ìbínú Olúwa gbóná si àwọn ènìyàn rẹ̀,
ó ti gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè, ó sì lù wọ́n bolẹ̀.
Àwọn òkè sì wárìrì,
òkú wọn sì dàbí ààtàn ní àárín ìgboro.
Pẹ̀lú gbogbo èyí, ìbínú rẹ̀ kò yí kúrò,
ṣùgbọ́n ọ̀wọ́ rẹ̀ sì ná jáde síbẹ̀. 26Yóò sì gbé ọ̀págun sókè sí àwọn orílẹ̀-èdè tí ó jìnnà,
yóò sì kọ sí wọn tí ó wà ní ìpẹ̀kun ilẹ̀.
Sì kíyèsi, wọ́n yóò yára wá kánkán. 27Kò sí ẹni tí yóò rẹ̀ nínú wọn, tàbí tí yóò kọsẹ̀,
kò sí ẹni tí yóò tòògbé tàbí tí yóò sùn;
bẹ́ẹ̀ ni àmùrè ẹ̀gbẹ́ wọn kì yóò tú,
bẹ́ẹ̀ ni okùn sálúbàtà wọn kì yóò ja. 28Àwọn ọfà wọn múná,
gbogbo ọrun wọn sì le;
pátákò àwọn ẹṣin wọn le bí òkúta akọ,
àwọn àgbá kẹ̀kẹ́ wọn sì dàbí ìjì líle.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.