Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nítorí náà, gẹ́gẹ́ bí ahọ́n iná ṣe ń jó àgékù koríko run àti bí koríko ṣe rẹlẹ̀ wẹ̀sì nínú iná, bẹ́ẹ̀ ni egbò wọn yóò jẹrà tí òdodo wọn yóò sì fẹ́ lọ bí eruku: nítorí pé wọ́n ti kọ òfin Olúwa àwọn ọmọ-ogun sílẹ̀ wọ́n sì gan ọ̀rọ̀ Ẹni mímọ́ Israẹli.

Isaiah 5:24 in English

Isaiah 5:24 · Berean Standard Bible

Therefore, as a tongue of fire consumes the straw, and as dry grass shrivels in the flame, so their roots will decay and their blossoms will blow away like dust; for they have rejected the instruction of the LORD of Hosts and despised the word of the Holy One of Israel.

Context

22Ègbé ni fún àwọn akọni nínú wáìnì mímu àti àwọn akíkanjú nínú àdàlú ọtí, 23tí wọ́n dá ẹlẹ́bi sílẹ̀ nítorí àbẹ̀tẹ́lẹ̀, tí wọn sì du aláre ní ẹ̀tọ́. 24Nítorí náà, gẹ́gẹ́ bí ahọ́n iná ṣe ń jó àgékù koríko run àti bí koríko ṣe rẹlẹ̀ wẹ̀sì nínú iná, bẹ́ẹ̀ ni egbò wọn yóò jẹrà tí òdodo wọn yóò sì fẹ́ lọ bí eruku: nítorí pé wọ́n ti kọ òfin Olúwa àwọn ọmọ-ogun sílẹ̀ wọ́n sì gan ọ̀rọ̀ Ẹni mímọ́ Israẹli. 25Nítorí náà, ìbínú Olúwa gbóná si àwọn ènìyàn rẹ̀, ó ti gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè, ó sì lù wọ́n bolẹ̀. Àwọn òkè sì wárìrì, òkú wọn sì dàbí ààtàn ní àárín ìgboro. Pẹ̀lú gbogbo èyí, ìbínú rẹ̀ kò yí kúrò, ṣùgbọ́n ọ̀wọ́ rẹ̀ sì ná jáde síbẹ̀. 26Yóò sì gbé ọ̀págun sókè sí àwọn orílẹ̀-èdè tí ó jìnnà, yóò sì kọ sí wọn tí ó wà ní ìpẹ̀kun ilẹ̀. Sì kíyèsi, wọ́n yóò yára wá kánkán.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.