Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ọgbà àjàrà sáré oko mẹ́wàá yóò mú ìkòkò wáìnì kan wá, nígbà tí òsùwọ̀n homeri kan yóò mú agbọ̀n irúgbìn kan wá.”

Isaiah 5:10 in English

Isaiah 5:10 · Berean Standard Bible

For ten acres of vineyard will yield but a bath of wine,* and a homer of seed only an ephah of grain.*”

Context

8Ègbé ni fún àwọn tí ń kọ́lé mọ́lé tí ó sì ń ra ilẹ̀ mọ́lẹ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí ààyè kò ṣẹ́kù tí ó sì nìkan gbé lórí ilẹ̀. 9Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti sọ ọ́ sí mi létí: “Ó dájú pé àwọn ilé ńlá ńlá yóò di ahoro, àwọn ilé dáradára yóò wà láìní olùgbé. 10Ọgbà àjàrà sáré oko mẹ́wàá yóò mú ìkòkò wáìnì kan wá, nígbà tí òsùwọ̀n homeri kan yóò mú agbọ̀n irúgbìn kan wá.” 11Ègbé ni fún àwọn tí wọ́n dìde ní kùtùkùtù òwúrọ̀ láti lépa ọtí líle, tí wọ́n sì mu ún títí alẹ́ fi lẹ́ títí wọ́n fi gbinájẹ pẹ̀lú wáìnì. 12Wọ́n ní dùùrù àti ohun èlò orin olókùn níbi àsè wọn, ṣaworo òun fèrè àti wáìnì, ṣùgbọ́n wọn kò ka iṣẹ́ Olúwa sí, wọn kò sí bọ̀wọ̀ fún iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.