Isaiah 5:11
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ègbé ni fún àwọn tí wọ́n dìde ní kùtùkùtù òwúrọ̀ láti lépa ọtí líle, tí wọ́n sì mu ún títí alẹ́ fi lẹ́ títí wọ́n fi gbinájẹ pẹ̀lú wáìnì.
Isaiah 5:11 in English
Isaiah 5:11 · Berean Standard Bible
Woe to those who rise early in the morning in pursuit of strong drink, who linger into the evening, to be inflamed by wine.
Context
9Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti sọ ọ́ sí mi létí:
“Ó dájú pé àwọn ilé ńlá ńlá
yóò di ahoro, àwọn ilé dáradára yóò wà láìní olùgbé. 10Ọgbà àjàrà sáré oko mẹ́wàá yóò mú
ìkòkò wáìnì kan wá,
nígbà tí òsùwọ̀n homeri kan yóò mú
agbọ̀n irúgbìn kan wá.” 11Ègbé ni fún àwọn tí wọ́n dìde
ní kùtùkùtù òwúrọ̀
láti lépa ọtí líle,
tí wọ́n sì mu ún títí alẹ́ fi lẹ́
títí wọ́n fi gbinájẹ pẹ̀lú wáìnì. 12Wọ́n ní dùùrù àti ohun èlò orin olókùn níbi àsè wọn,
ṣaworo òun fèrè àti wáìnì,
ṣùgbọ́n wọn kò ka iṣẹ́ Olúwa sí,
wọn kò sí bọ̀wọ̀ fún iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀. 13Nítorí náà àwọn ènìyàn mi yóò lọ sí ìgbèkùn
nítorí òye kò sí fún wọn,
ebi ni yóò pa àwọn ọlọ́lá wọn kú;
ẹgbàágbèje wọn ni òǹgbẹ yóò sì gbẹ.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.