Isaiah 5:8
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ègbé ni fún àwọn tí ń kọ́lé mọ́lé tí ó sì ń ra ilẹ̀ mọ́lẹ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí ààyè kò ṣẹ́kù tí ó sì nìkan gbé lórí ilẹ̀.
Isaiah 5:8 in English
Isaiah 5:8 · Berean Standard Bible
Woe to you who add house to house and join field to field until no place is left and you live alone in the land.
Context
6Èmi yóò sì sọ ọ́ di ahoro
láì kọ ọ́ láì ro ó,
ẹ̀wọ̀n àti ẹ̀gún ni yóò hù níbẹ̀.
Èmi yóò sì pàṣẹ fún kurukuru
láti má ṣe rọ̀jò sórí i rẹ̀.” 7Ọgbà àjàrà Olúwa àwọn ọmọ-ogun
ni ilé Israẹli
àwọn ọkùnrin Juda
sì ni àyànfẹ́ ọgbà rẹ̀.
Ó retí ìdájọ́ ẹ̀tọ́ ṣùgbọ́n, ìtàjẹ̀ sílẹ̀ ni ó rí.
Òun ń retí òdodo ṣùgbọ́n ó gbọ́ ẹkún ìpayínkeke. 8Ègbé ni fún àwọn tí ń kọ́lé mọ́lé
tí ó sì ń ra ilẹ̀ mọ́lẹ̀
tó bẹ́ẹ̀ tí ààyè kò ṣẹ́kù
tí ó sì nìkan gbé lórí ilẹ̀. 9Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti sọ ọ́ sí mi létí:
“Ó dájú pé àwọn ilé ńlá ńlá
yóò di ahoro, àwọn ilé dáradára yóò wà láìní olùgbé. 10Ọgbà àjàrà sáré oko mẹ́wàá yóò mú
ìkòkò wáìnì kan wá,
nígbà tí òsùwọ̀n homeri kan yóò mú
agbọ̀n irúgbìn kan wá.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.