Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ọgbà àjàrà Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni ilé Israẹli àwọn ọkùnrin Juda sì ni àyànfẹ́ ọgbà rẹ̀. Ó retí ìdájọ́ ẹ̀tọ́ ṣùgbọ́n, ìtàjẹ̀ sílẹ̀ ni ó rí. Òun ń retí òdodo ṣùgbọ́n ó gbọ́ ẹkún ìpayínkeke.

Isaiah 5:7 in English

Isaiah 5:7 · Berean Standard Bible

For the vineyard of the LORD of Hosts is the house of Israel, and the men of Judah are the plant of His delight. He looked for justice, but saw bloodshed; for righteousness, but heard a cry of distress.

Context

5Ní ìsinsin yìí, èmi yóò wí fún ọ ohun tí n ó ṣe sí ọgbà àjàrà mi. Èmi yóò gé igi inú rẹ̀ kúrò, a ó sì pa á run, Èmi yóò wó ògiri rẹ̀ lulẹ̀ yóò sì di ìtẹ̀mọ́lẹ̀. 6Èmi yóò sì sọ ọ́ di ahoro láì kọ ọ́ láì ro ó, ẹ̀wọ̀n àti ẹ̀gún ni yóò hù níbẹ̀. Èmi yóò sì pàṣẹ fún kurukuru láti má ṣe rọ̀jò sórí i rẹ̀.” 7Ọgbà àjàrà Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni ilé Israẹli àwọn ọkùnrin Juda sì ni àyànfẹ́ ọgbà rẹ̀. Ó retí ìdájọ́ ẹ̀tọ́ ṣùgbọ́n, ìtàjẹ̀ sílẹ̀ ni ó rí. Òun ń retí òdodo ṣùgbọ́n ó gbọ́ ẹkún ìpayínkeke. 8Ègbé ni fún àwọn tí ń kọ́lé mọ́lé tí ó sì ń ra ilẹ̀ mọ́lẹ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí ààyè kò ṣẹ́kù tí ó sì nìkan gbé lórí ilẹ̀. 9Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti sọ ọ́ sí mi létí: “Ó dájú pé àwọn ilé ńlá ńlá yóò di ahoro, àwọn ilé dáradára yóò wà láìní olùgbé.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.