Isaiah 41:17
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Àwọn tálákà àti aláìní wá omi, ṣùgbọ́n kò sí; ahọ́n wọn gbẹ fún òǹgbẹ. Ṣùgbọ́n Èmi Olúwa yóò dá wọn lóhùn; Èmi, Ọlọ́run Israẹli, kì yóò kọ̀ wọ́n sílẹ̀.
Isaiah 41:17 in English
Isaiah 41:17 · Berean Standard Bible
The poor and needy seek water, but there is none; their tongues are parched with thirst. I, the LORD, will answer them; I, the God of Israel, will not forsake them.
Context
15“Kíyèsi, Èmi yóò sọ ọ́ di òòlù ìpakà tuntun,
tí ó mú ti eyín rẹ̀ mú, ìwọ yóò lu àwọn òkè ńlá,
ìwọ yóò fọ́ wọn túútúú,
a ó sì sọ òkè kékeré di ìyàngbò. 16Ìwọ yóò fẹ́ wọn, afẹ́fẹ́ yóò sì gbá wọn mú,
àti ẹ̀fúùfù yóò sì fẹ́ wọn dànù.
Ṣùgbọ́n ìwọ yóò yọ̀ nínú Olúwa
ìwọ yóò sì ṣògo nínú Ẹni Mímọ́ ti Israẹli. 17“Àwọn tálákà àti aláìní wá omi,
ṣùgbọ́n kò sí;
ahọ́n wọn gbẹ fún òǹgbẹ.
Ṣùgbọ́n Èmi Olúwa yóò dá wọn lóhùn;
Èmi, Ọlọ́run Israẹli, kì yóò kọ̀ wọ́n sílẹ̀. 18Èmi yóò mú kí odò kí ó sàn ní ibi gíga
àti orísun omi ní àárín àfonífojì.
Èmi yóò sọ aṣálẹ̀ di adágún omi,
àti ilẹ̀ tí ó gbẹ gidigidi di orísun omi. 19Èmi yóò fi sínú aṣálẹ̀
igi kedari àti kasia, maritili àti olifi.
Èmi yóò gbin junifa sí inú aginjù,
igi firi àti sípírẹ́ṣì papọ̀
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.