Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ìwọ yóò fẹ́ wọn, afẹ́fẹ́ yóò sì gbá wọn mú, àti ẹ̀fúùfù yóò sì fẹ́ wọn dànù. Ṣùgbọ́n ìwọ yóò yọ̀ nínú Olúwa ìwọ yóò sì ṣògo nínú Ẹni Mímọ́ ti Israẹli.

Isaiah 41:16 in English

Isaiah 41:16 · Berean Standard Bible

You will winnow them, and a wind will carry them away; a gale will scatter them. But you will rejoice in the LORD; you will glory in the Holy One of Israel.

Context

14Má ṣe bẹ̀rù, ìwọ Jakọbu kòkòrò, ìwọ Israẹli kékeré, nítorí Èmi fúnra mi yóò ràn ọ́ lọ́wọ́,” ni Olúwa wí, olùdáǹdè rẹ, Ẹni Mímọ́ ti Israẹli. 15“Kíyèsi, Èmi yóò sọ ọ́ di òòlù ìpakà tuntun, tí ó mú ti eyín rẹ̀ mú, ìwọ yóò lu àwọn òkè ńlá, ìwọ yóò fọ́ wọn túútúú, a ó sì sọ òkè kékeré di ìyàngbò. 16Ìwọ yóò fẹ́ wọn, afẹ́fẹ́ yóò sì gbá wọn mú, àti ẹ̀fúùfù yóò sì fẹ́ wọn dànù. Ṣùgbọ́n ìwọ yóò yọ̀ nínú Olúwa ìwọ yóò sì ṣògo nínú Ẹni Mímọ́ ti Israẹli. 17“Àwọn tálákà àti aláìní wá omi, ṣùgbọ́n kò sí; ahọ́n wọn gbẹ fún òǹgbẹ. Ṣùgbọ́n Èmi Olúwa yóò dá wọn lóhùn; Èmi, Ọlọ́run Israẹli, kì yóò kọ̀ wọ́n sílẹ̀. 18Èmi yóò mú kí odò kí ó sàn ní ibi gíga àti orísun omi ní àárín àfonífojì. Èmi yóò sọ aṣálẹ̀ di adágún omi, àti ilẹ̀ tí ó gbẹ gidigidi di orísun omi.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.