Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Kíyèsi, Èmi yóò sọ ọ́ di òòlù ìpakà tuntun, tí ó mú ti eyín rẹ̀ mú, ìwọ yóò lu àwọn òkè ńlá, ìwọ yóò fọ́ wọn túútúú, a ó sì sọ òkè kékeré di ìyàngbò.

Isaiah 41:15 in English

Isaiah 41:15 · Berean Standard Bible

Behold, I will make you into a threshing sledge, new and sharp, with many teeth. You will thresh the mountains and crush them, and reduce the hills to chaff.

Context

13Nítorí Èmi ni Olúwa Ọlọ́run rẹ, tí ó di ọwọ́ ọ̀tún rẹ mú tí ó sì sọ fún ọ pé, má ṣe bẹ̀rù; Èmi yóò ràn ọ́ lọ́wọ́. 14Má ṣe bẹ̀rù, ìwọ Jakọbu kòkòrò, ìwọ Israẹli kékeré, nítorí Èmi fúnra mi yóò ràn ọ́ lọ́wọ́,” ni Olúwa wí, olùdáǹdè rẹ, Ẹni Mímọ́ ti Israẹli. 15“Kíyèsi, Èmi yóò sọ ọ́ di òòlù ìpakà tuntun, tí ó mú ti eyín rẹ̀ mú, ìwọ yóò lu àwọn òkè ńlá, ìwọ yóò fọ́ wọn túútúú, a ó sì sọ òkè kékeré di ìyàngbò. 16Ìwọ yóò fẹ́ wọn, afẹ́fẹ́ yóò sì gbá wọn mú, àti ẹ̀fúùfù yóò sì fẹ́ wọn dànù. Ṣùgbọ́n ìwọ yóò yọ̀ nínú Olúwa ìwọ yóò sì ṣògo nínú Ẹni Mímọ́ ti Israẹli. 17“Àwọn tálákà àti aláìní wá omi, ṣùgbọ́n kò sí; ahọ́n wọn gbẹ fún òǹgbẹ. Ṣùgbọ́n Èmi Olúwa yóò dá wọn lóhùn; Èmi, Ọlọ́run Israẹli, kì yóò kọ̀ wọ́n sílẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.