Isaiah 41:13
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nítorí Èmi ni Olúwa Ọlọ́run rẹ, tí ó di ọwọ́ ọ̀tún rẹ mú tí ó sì sọ fún ọ pé, má ṣe bẹ̀rù; Èmi yóò ràn ọ́ lọ́wọ́.
Isaiah 41:13 in English
Isaiah 41:13 · Berean Standard Bible
For I am the LORD your God, who takes hold of your right hand and tells you: Do not fear, I will help you.
Context
11“Gbogbo àwọn tí ó bínú sí ọ
ni ojú yóò tì, tí wọn yóò sì di ẹlẹ́yà;
àwọn tó ń bá ọ jà
yóò dàbí asán, wọn yóò ṣègbé. 12Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwọ yóò wá àwọn ọ̀tá rẹ,
ìwọ kì yóò rí wọn.
Gbogbo àwọn tí ó gbóguntì ọ́
yóò dàbí ohun tí kò sí. 13Nítorí Èmi ni Olúwa Ọlọ́run rẹ,
tí ó di ọwọ́ ọ̀tún rẹ mú
tí ó sì sọ fún ọ pé, má ṣe bẹ̀rù;
Èmi yóò ràn ọ́ lọ́wọ́. 14Má ṣe bẹ̀rù, ìwọ Jakọbu kòkòrò,
ìwọ Israẹli kékeré,
nítorí Èmi fúnra mi yóò ràn ọ́ lọ́wọ́,”
ni Olúwa wí,
olùdáǹdè rẹ, Ẹni Mímọ́ ti Israẹli. 15“Kíyèsi, Èmi yóò sọ ọ́ di òòlù ìpakà tuntun,
tí ó mú ti eyín rẹ̀ mú, ìwọ yóò lu àwọn òkè ńlá,
ìwọ yóò fọ́ wọn túútúú,
a ó sì sọ òkè kékeré di ìyàngbò.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.