Isaiah 41:11
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Gbogbo àwọn tí ó bínú sí ọ ni ojú yóò tì, tí wọn yóò sì di ẹlẹ́yà; àwọn tó ń bá ọ jà yóò dàbí asán, wọn yóò ṣègbé.
Isaiah 41:11 in English
Isaiah 41:11 · Berean Standard Bible
Behold, all who rage against you will be ashamed and disgraced; those who contend with you will be reduced to nothing and will perish.
Context
9mo mú ọ láti ìpẹ̀kun ilẹ̀ ayé,
láti kọ̀rọ̀ rẹ̀ tí ó jìnnà jùlọ ni mo ti pè ọ́.
Èmi wí pé, ‘Ìwọ ni ìránṣẹ́ mi’;
Èmi ti yàn ọ́ bẹ́ẹ̀ ni èmi kò sì tí ì kọ̀ ọ́ sílẹ̀. 10Nítorí náà má bẹ̀rù, nítorí èmi wà pẹ̀lú rẹ;
má ṣe jẹ́ kí àyà kí ó fò ọ́, nítorí èmi ni Ọlọ́run rẹ.
Èmi yóò fún ọ lókun èmi ó sì ràn ọ́ lọ́wọ́.
Èmi ó gbé ọ ró pẹ̀lú ọwọ́ ọ̀tún òdodo mi. 11“Gbogbo àwọn tí ó bínú sí ọ
ni ojú yóò tì, tí wọn yóò sì di ẹlẹ́yà;
àwọn tó ń bá ọ jà
yóò dàbí asán, wọn yóò ṣègbé. 12Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwọ yóò wá àwọn ọ̀tá rẹ,
ìwọ kì yóò rí wọn.
Gbogbo àwọn tí ó gbóguntì ọ́
yóò dàbí ohun tí kò sí. 13Nítorí Èmi ni Olúwa Ọlọ́run rẹ,
tí ó di ọwọ́ ọ̀tún rẹ mú
tí ó sì sọ fún ọ pé, má ṣe bẹ̀rù;
Èmi yóò ràn ọ́ lọ́wọ́.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.