Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ó ń tọ́ àwọn agbo rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́-àgùntàn: Ó kó àwọn ọ̀dọ́-àgùntàn ní apá rẹ̀. Ó sì gbé wọn súnmọ́ oókan àyà rẹ̀; ó sì fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ darí àwọn tí ó ní.

Isaiah 40:11 in English

Isaiah 40:11 · Berean Standard Bible

He tends His flock like a shepherd; He gathers the lambs in His arms and carries them close to His heart. He gently leads the nursing ewes.

Context

9Ìwọ tí o mú ìyìn ayọ̀ wá sí Sioni, lọ sí orí òkè gíga. Ìwọ tí ó mú ìyìn ayọ̀ wá sí Jerusalẹmu, gbé ohùn rẹ sókè pẹ̀lú ariwo, gbé e sókè, má ṣe bẹ̀rù; sọ fún àwọn ìlú u Juda, “Ọlọ́run rẹ nìyìí!” 10Wò ó, Olúwa Olódùmarè náà ń bọ̀ wá pẹ̀lú agbára, apá rẹ̀ sì ń jẹ ọba fún un. Wò ó, èrè rẹ̀ sì wà pẹ̀lú rẹ̀, àti ìdápadà rẹ̀ tí ń bá a bọ̀ wá. 11Ó ń tọ́ àwọn agbo rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́-àgùntàn: Ó kó àwọn ọ̀dọ́-àgùntàn ní apá rẹ̀. Ó sì gbé wọn súnmọ́ oókan àyà rẹ̀; ó sì fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ darí àwọn tí ó ní. 12Ta ni ó tiwọn omi nínú kòtò ọwọ́ rẹ̀, tàbí pẹ̀lú ìbú ọwọ́ rẹ̀ tí ó wọn àwọn ọ̀run? Ta ni ó ti kó erùpẹ̀ ilẹ̀ ayé jọ nínú apẹ̀rẹ̀, tàbí kí ó wọn àwọn òkè ńlá lórí ìwọ̀n àti òkè kéékèèké nínú òsùwọ̀n? 13Ta ni ó ti mọ ọkàn Olúwa, tàbí tí ó ti tọ́ ọ ṣọ́nà gẹ́gẹ́ bí olùdámọ̀ràn rẹ̀?

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.