Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Wò ó, Olúwa Olódùmarè náà ń bọ̀ wá pẹ̀lú agbára, apá rẹ̀ sì ń jẹ ọba fún un. Wò ó, èrè rẹ̀ sì wà pẹ̀lú rẹ̀, àti ìdápadà rẹ̀ tí ń bá a bọ̀ wá.

Isaiah 40:10 in English

Isaiah 40:10 · Berean Standard Bible

Behold, the Lord GOD comes with might, and His arm establishes His rule. His reward is with Him, and His recompense accompanies Him.

Context

8Koríko ń rọ ìtànná sì ń rẹ̀, ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wa dúró títí láé.” 9Ìwọ tí o mú ìyìn ayọ̀ wá sí Sioni, lọ sí orí òkè gíga. Ìwọ tí ó mú ìyìn ayọ̀ wá sí Jerusalẹmu, gbé ohùn rẹ sókè pẹ̀lú ariwo, gbé e sókè, má ṣe bẹ̀rù; sọ fún àwọn ìlú u Juda, “Ọlọ́run rẹ nìyìí!” 10Wò ó, Olúwa Olódùmarè náà ń bọ̀ wá pẹ̀lú agbára, apá rẹ̀ sì ń jẹ ọba fún un. Wò ó, èrè rẹ̀ sì wà pẹ̀lú rẹ̀, àti ìdápadà rẹ̀ tí ń bá a bọ̀ wá. 11Ó ń tọ́ àwọn agbo rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́-àgùntàn: Ó kó àwọn ọ̀dọ́-àgùntàn ní apá rẹ̀. Ó sì gbé wọn súnmọ́ oókan àyà rẹ̀; ó sì fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ darí àwọn tí ó ní. 12Ta ni ó tiwọn omi nínú kòtò ọwọ́ rẹ̀, tàbí pẹ̀lú ìbú ọwọ́ rẹ̀ tí ó wọn àwọn ọ̀run? Ta ni ó ti kó erùpẹ̀ ilẹ̀ ayé jọ nínú apẹ̀rẹ̀, tàbí kí ó wọn àwọn òkè ńlá lórí ìwọ̀n àti òkè kéékèèké nínú òsùwọ̀n?

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.