Isaiah 40:13
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ta ni ó ti mọ ọkàn Olúwa, tàbí tí ó ti tọ́ ọ ṣọ́nà gẹ́gẹ́ bí olùdámọ̀ràn rẹ̀?
Isaiah 40:13 in English
Isaiah 40:13 · Berean Standard Bible
Who has directed the Spirit of the LORD,* or informed Him as His counselor?*
Context
11Ó ń tọ́ àwọn agbo rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́-àgùntàn:
Ó kó àwọn ọ̀dọ́-àgùntàn ní apá rẹ̀.
Ó sì gbé wọn súnmọ́ oókan àyà rẹ̀;
ó sì fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ darí àwọn tí ó ní. 12Ta ni ó tiwọn omi nínú kòtò ọwọ́ rẹ̀,
tàbí pẹ̀lú ìbú ọwọ́ rẹ̀
tí ó wọn àwọn ọ̀run?
Ta ni ó ti kó erùpẹ̀ ilẹ̀ ayé jọ nínú apẹ̀rẹ̀,
tàbí kí ó wọn àwọn òkè ńlá lórí ìwọ̀n
àti òkè kéékèèké nínú òsùwọ̀n? 13Ta ni ó ti mọ ọkàn Olúwa,
tàbí tí ó ti tọ́ ọ ṣọ́nà gẹ́gẹ́ bí olùdámọ̀ràn rẹ̀? 14Ta ni Olúwa ké sí kí ó là á lọ́yẹ
àti ta ni ó kọ́ òun ní ọ̀nà tí ó tọ́?
Ta ni ẹni náà tí ó kọ́ ọ ní ọgbọ́n
tàbí tí ó fi ipa ọ̀nà òye hàn án? 15Nítòótọ́ àwọn orílẹ̀-èdè dàbí i ẹ̀kún omi nínú garawa;
a kà wọ́n sí gẹ́gẹ́ bí eruku lórí ìwọ̀n;
ó wọn àwọn erékùṣù àfi bí eruku múnúmúnú ni wọ́n.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.