Isaiah 40:15
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nítòótọ́ àwọn orílẹ̀-èdè dàbí i ẹ̀kún omi nínú garawa; a kà wọ́n sí gẹ́gẹ́ bí eruku lórí ìwọ̀n; ó wọn àwọn erékùṣù àfi bí eruku múnúmúnú ni wọ́n.
Isaiah 40:15 in English
Isaiah 40:15 · Berean Standard Bible
Surely the nations are like a drop in a bucket; they are considered a speck of dust on the scales; He lifts up the islands * like fine dust.
Context
13Ta ni ó ti mọ ọkàn Olúwa,
tàbí tí ó ti tọ́ ọ ṣọ́nà gẹ́gẹ́ bí olùdámọ̀ràn rẹ̀? 14Ta ni Olúwa ké sí kí ó là á lọ́yẹ
àti ta ni ó kọ́ òun ní ọ̀nà tí ó tọ́?
Ta ni ẹni náà tí ó kọ́ ọ ní ọgbọ́n
tàbí tí ó fi ipa ọ̀nà òye hàn án? 15Nítòótọ́ àwọn orílẹ̀-èdè dàbí i ẹ̀kún omi nínú garawa;
a kà wọ́n sí gẹ́gẹ́ bí eruku lórí ìwọ̀n;
ó wọn àwọn erékùṣù àfi bí eruku múnúmúnú ni wọ́n. 16Lebanoni kò tó fún pẹpẹ iná,
tàbí kí àwọn ẹranko rẹ̀ kí ó tó fún ẹbọ sísun. 17Níwájú rẹ̀ ni gbogbo orílẹ̀-èdè dàbí ohun tí kò sí;
gbogbo wọn ló kà sí ohun tí kò wúlò
tí kò tó ohun tí kò sí.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.