Isaiah 40:17
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Níwájú rẹ̀ ni gbogbo orílẹ̀-èdè dàbí ohun tí kò sí; gbogbo wọn ló kà sí ohun tí kò wúlò tí kò tó ohun tí kò sí.
Isaiah 40:17 in English
Isaiah 40:17 · Berean Standard Bible
All the nations are as nothing before Him; He regards them as nothingness and emptiness.
Context
15Nítòótọ́ àwọn orílẹ̀-èdè dàbí i ẹ̀kún omi nínú garawa;
a kà wọ́n sí gẹ́gẹ́ bí eruku lórí ìwọ̀n;
ó wọn àwọn erékùṣù àfi bí eruku múnúmúnú ni wọ́n. 16Lebanoni kò tó fún pẹpẹ iná,
tàbí kí àwọn ẹranko rẹ̀ kí ó tó fún ẹbọ sísun. 17Níwájú rẹ̀ ni gbogbo orílẹ̀-èdè dàbí ohun tí kò sí;
gbogbo wọn ló kà sí ohun tí kò wúlò
tí kò tó ohun tí kò sí. 18Ta ni nígbà náà tí ìwọ yóò fi Ọlọ́run wé?
Ère wo ni ìwọ yóò fi ṣe àkàwé rẹ̀? 19Ní ti ère, oníṣọ̀nà ni ó dà á,
ti alágbẹ̀dẹ wúrà sì fi wúrà bò ó
tí a sì ṣe ẹ̀wọ̀n ọ̀nà sílífà fún un.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.