Isaiah 40:19
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ní ti ère, oníṣọ̀nà ni ó dà á, ti alágbẹ̀dẹ wúrà sì fi wúrà bò ó tí a sì ṣe ẹ̀wọ̀n ọ̀nà sílífà fún un.
Isaiah 40:19 in English
Isaiah 40:19 · Berean Standard Bible
To an idol that a craftsman casts and a metalworker overlays with gold and fits with silver chains?
Context
17Níwájú rẹ̀ ni gbogbo orílẹ̀-èdè dàbí ohun tí kò sí;
gbogbo wọn ló kà sí ohun tí kò wúlò
tí kò tó ohun tí kò sí. 18Ta ni nígbà náà tí ìwọ yóò fi Ọlọ́run wé?
Ère wo ni ìwọ yóò fi ṣe àkàwé rẹ̀? 19Ní ti ère, oníṣọ̀nà ni ó dà á,
ti alágbẹ̀dẹ wúrà sì fi wúrà bò ó
tí a sì ṣe ẹ̀wọ̀n ọ̀nà sílífà fún un. 20Ọkùnrin kan tí ó tálákà jù kí ó lè mú
irú ọrẹ bẹ́ẹ̀ wá,
wá igi tí kò le è rà.
Ó wá oníṣọ̀nà tí ó
láti ṣe àgbékalẹ̀ ère tí kì yóò le è ṣubú. 21Ǹjẹ́ o kò tí ì mọ̀
ìwọ kò tí ì gbọ́?
A kò tí ì sọ fún ọ láti ìbẹ̀rẹ̀ wá?
Ìwọ kò tí ì mọ láti ìgbà ìpìlẹ̀ ayé?
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.