Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ìkógun rẹ, ìwọ orílẹ̀-èdè ni a kórè gẹ́gẹ́ bí i ti ọ̀dọ́ eṣú; gẹ́gẹ́ bí àkójọpọ̀ eṣú, àwọn ènìyàn wọ ibẹ̀.

Isaiah 33:4 in English

Isaiah 33:4 · Berean Standard Bible

Your spoil, O nations, * is gathered as by locusts; like a swarm of locusts men sweep over it.

Context

2Olúwa ṣàánú fún wa àwa ń ṣàfẹ́rí i rẹ. Máa jẹ́ agbára wa ní òròòwúrọ̀ ìgbàlà wa ní àsìkò ìpọ́njú. 3Ní ìkérara ohùn rẹ, àwọn ènìyàn sá, nígbà tí o dìde sókè, àwọn orílẹ̀-èdè fọ́nká. 4Ìkógun rẹ, ìwọ orílẹ̀-èdè ni a kórè gẹ́gẹ́ bí i ti ọ̀dọ́ eṣú; gẹ́gẹ́ bí àkójọpọ̀ eṣú, àwọn ènìyàn wọ ibẹ̀. 5A gbé Olúwa ga, nítorí pé ó ń gbé ibi gíga, Òun yóò kún Sioni pẹ̀lú ẹ̀tọ́ àti òdodo. 6Òun yóò jẹ́ ìpìlẹ̀ tí ó dájú fún àkókò rẹ ibùjókòó ìgbàlà kíkún àti ọgbọ́n òun ìmọ̀; ìbẹ̀rù Olúwa ni kọ́kọ́rọ́ sí ìṣúra yìí.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.