Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

A gbé Olúwa ga, nítorí pé ó ń gbé ibi gíga, Òun yóò kún Sioni pẹ̀lú ẹ̀tọ́ àti òdodo.

Isaiah 33:5 in English

Isaiah 33:5 · Berean Standard Bible

The LORD is exalted, for He dwells on high; He has filled Zion with justice and righteousness.

Context

3Ní ìkérara ohùn rẹ, àwọn ènìyàn sá, nígbà tí o dìde sókè, àwọn orílẹ̀-èdè fọ́nká. 4Ìkógun rẹ, ìwọ orílẹ̀-èdè ni a kórè gẹ́gẹ́ bí i ti ọ̀dọ́ eṣú; gẹ́gẹ́ bí àkójọpọ̀ eṣú, àwọn ènìyàn wọ ibẹ̀. 5A gbé Olúwa ga, nítorí pé ó ń gbé ibi gíga, Òun yóò kún Sioni pẹ̀lú ẹ̀tọ́ àti òdodo. 6Òun yóò jẹ́ ìpìlẹ̀ tí ó dájú fún àkókò rẹ ibùjókòó ìgbàlà kíkún àti ọgbọ́n òun ìmọ̀; ìbẹ̀rù Olúwa ni kọ́kọ́rọ́ sí ìṣúra yìí. 7Wò ó, àwọn onígboyà ọkùnrin wọn pohùnréré ẹkún ní òpópónà; àwọn ikọ̀ àlàáfíà sọkún kíkorò.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.