Isaiah 33:3
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ní ìkérara ohùn rẹ, àwọn ènìyàn sá, nígbà tí o dìde sókè, àwọn orílẹ̀-èdè fọ́nká.
Isaiah 33:3 in English
Isaiah 33:3 · Berean Standard Bible
The peoples flee the thunder of Your voice; the nations scatter when You rise.
Context
1Ègbé ni fún ọ, ìwọ apanirun,
ìwọ tí a kò tí ì parun!
Ègbé ni fún ọ, ìwọ ọ̀dàlẹ̀,
ìwọ tí a kò tí ì dà ọ́!
Nígbà tí o bá dẹ́kun à ń pa ni run;
a ó pa ìwọ náà run,
nígbà tí o bá dẹ́kun à ń dani,
a ó da ìwọ náà. 2Olúwa ṣàánú fún wa
àwa ń ṣàfẹ́rí i rẹ.
Máa jẹ́ agbára wa ní òròòwúrọ̀
ìgbàlà wa ní àsìkò ìpọ́njú. 3Ní ìkérara ohùn rẹ, àwọn ènìyàn sá,
nígbà tí o dìde sókè, àwọn orílẹ̀-èdè fọ́nká. 4Ìkógun rẹ, ìwọ orílẹ̀-èdè ni a kórè
gẹ́gẹ́ bí i ti ọ̀dọ́ eṣú;
gẹ́gẹ́ bí àkójọpọ̀ eṣú, àwọn ènìyàn wọ ibẹ̀. 5A gbé Olúwa ga, nítorí pé ó ń gbé ibi gíga,
Òun yóò kún Sioni pẹ̀lú ẹ̀tọ́ àti òdodo.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.