Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Olúwa ṣàánú fún wa àwa ń ṣàfẹ́rí i rẹ. Máa jẹ́ agbára wa ní òròòwúrọ̀ ìgbàlà wa ní àsìkò ìpọ́njú.

Isaiah 33:2 in English

Isaiah 33:2 · Berean Standard Bible

O LORD, be gracious to us! We wait for You. Be our strength every morning and our salvation in time of trouble.

Context

1Ègbé ni fún ọ, ìwọ apanirun, ìwọ tí a kò tí ì parun! Ègbé ni fún ọ, ìwọ ọ̀dàlẹ̀, ìwọ tí a kò tí ì dà ọ́! Nígbà tí o bá dẹ́kun à ń pa ni run; a ó pa ìwọ náà run, nígbà tí o bá dẹ́kun à ń dani, a ó da ìwọ náà. 2Olúwa ṣàánú fún wa àwa ń ṣàfẹ́rí i rẹ. Máa jẹ́ agbára wa ní òròòwúrọ̀ ìgbàlà wa ní àsìkò ìpọ́njú. 3Ní ìkérara ohùn rẹ, àwọn ènìyàn sá, nígbà tí o dìde sókè, àwọn orílẹ̀-èdè fọ́nká. 4Ìkógun rẹ, ìwọ orílẹ̀-èdè ni a kórè gẹ́gẹ́ bí i ti ọ̀dọ́ eṣú; gẹ́gẹ́ bí àkójọpọ̀ eṣú, àwọn ènìyàn wọ ibẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.