Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ní ọjọ́ náà, Olúwa yóò já ọ̀ṣọ́ wọn gbà kúrò ti ọwọ́ àti gèlè àti ẹ̀gbà ọrùn tí ó dàbí òṣùpá

Isaiah 3:18 in English

Isaiah 3:18 · Berean Standard Bible

In that day the Lord will take away their finery: their anklets and headbands and crescents;

Context

16Olúwa wí pé, “Àwọn obìnrin Sioni jẹ́ agbéraga, wọn ń rìn lọ pẹ̀lú ọrùn tí ó nà tàntàn, tí wọn ń fojú pe ọkùnrin, tí wọn ń sọ̀dí bí wọ́n ti ń yan lọ pẹ̀lú ohun ọ̀ṣọ́ tí ń mì wọnjanwọnjan lọ́rùn ẹsẹ̀ wọn. 17Nítorí náà Olúwa yóò mú egbò wá sórí àwọn obìnrin Sioni, Olúwa yóò sì pá wọn ní agbárí.” 18Ní ọjọ́ náà, Olúwa yóò já ọ̀ṣọ́ wọn gbà kúrò ti ọwọ́ àti gèlè àti ẹ̀gbà ọrùn tí ó dàbí òṣùpá 19gbogbo yẹtí, ẹ̀gbà ọwọ́ àti ìbòjú, 20gbogbo gèlè, ẹ̀gbà ọrùn, ẹsẹ̀ àti àyà, àwọn ìgò tùràrí àti òògùn,

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.