Isaiah 3:16
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Olúwa wí pé, “Àwọn obìnrin Sioni jẹ́ agbéraga, wọn ń rìn lọ pẹ̀lú ọrùn tí ó nà tàntàn, tí wọn ń fojú pe ọkùnrin, tí wọn ń sọ̀dí bí wọ́n ti ń yan lọ pẹ̀lú ohun ọ̀ṣọ́ tí ń mì wọnjanwọnjan lọ́rùn ẹsẹ̀ wọn.
Isaiah 3:16 in English
Isaiah 3:16 · Berean Standard Bible
The LORD also says: “Because the daughters of Zion are haughty— walking with heads held high and wanton eyes, prancing and skipping as they go, jingling the bracelets on their ankles—
Context
14Olúwa dojú ẹjọ́ kọ
àwọn àgbàgbà àti àwọn olórí àwọn ènìyàn rẹ̀.
“Ẹ̀yin ni ẹ ti run ọgbà àjàrà mi,
ogún àwọn tálákà ń bẹ̀ nínú ilé yín. 15Kín ni èrò yín láti máa run àwọn ènìyàn mi túútúú
tí ẹ sì fojú àwọn tálákà ni gbolẹ̀?”
ni Olúwa wí, Olúwa àwọn ọmọ-ogun. 16Olúwa wí pé,
“Àwọn obìnrin Sioni jẹ́ agbéraga,
wọn ń rìn lọ pẹ̀lú ọrùn tí ó nà tàntàn,
tí wọn ń fojú pe ọkùnrin,
tí wọn ń sọ̀dí bí wọ́n ti ń yan lọ
pẹ̀lú ohun ọ̀ṣọ́ tí ń mì wọnjanwọnjan lọ́rùn ẹsẹ̀ wọn. 17Nítorí náà Olúwa yóò mú egbò wá sórí àwọn obìnrin Sioni,
Olúwa yóò sì pá wọn ní agbárí.” 18Ní ọjọ́ náà, Olúwa yóò já ọ̀ṣọ́ wọn gbà kúrò ti ọwọ́ àti gèlè àti ẹ̀gbà ọrùn tí ó dàbí òṣùpá
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.