Isaiah 3:15
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Kín ni èrò yín láti máa run àwọn ènìyàn mi túútúú tí ẹ sì fojú àwọn tálákà ni gbolẹ̀?” ni Olúwa wí, Olúwa àwọn ọmọ-ogun.
Isaiah 3:15 in English
Isaiah 3:15 · Berean Standard Bible
Why do you crush My people and grind the faces of the poor?” declares the Lord GOD of Hosts.
Context
13Olúwa bọ sí ipò rẹ̀ ní ìtẹ́ ìdájọ́
Ó dìde láti dá àwọn ènìyàn lẹ́jọ́. 14Olúwa dojú ẹjọ́ kọ
àwọn àgbàgbà àti àwọn olórí àwọn ènìyàn rẹ̀.
“Ẹ̀yin ni ẹ ti run ọgbà àjàrà mi,
ogún àwọn tálákà ń bẹ̀ nínú ilé yín. 15Kín ni èrò yín láti máa run àwọn ènìyàn mi túútúú
tí ẹ sì fojú àwọn tálákà ni gbolẹ̀?”
ni Olúwa wí, Olúwa àwọn ọmọ-ogun. 16Olúwa wí pé,
“Àwọn obìnrin Sioni jẹ́ agbéraga,
wọn ń rìn lọ pẹ̀lú ọrùn tí ó nà tàntàn,
tí wọn ń fojú pe ọkùnrin,
tí wọn ń sọ̀dí bí wọ́n ti ń yan lọ
pẹ̀lú ohun ọ̀ṣọ́ tí ń mì wọnjanwọnjan lọ́rùn ẹsẹ̀ wọn. 17Nítorí náà Olúwa yóò mú egbò wá sórí àwọn obìnrin Sioni,
Olúwa yóò sì pá wọn ní agbárí.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.