Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ní àìpẹ́ jọjọ, ǹjẹ́ a kò ní sọ Lebanoni di pápá ẹlẹ́tù lójú àti pápá ẹlẹ́tù lójú yóò dàbí aginjù?

Isaiah 29:17 in English

Isaiah 29:17 · Berean Standard Bible

In a very short time, will not Lebanon become an orchard, and the orchard seem like a forest?

Context

15Ègbé ni fún àwọn tí ó lọ sí ọ̀gbun láti fi ètò wọn pamọ́ kúrò lójú Olúwa, tí wọ́n ń ṣe iṣẹ́ ẹ wọn nínú òkùnkùn tí wọ́n sì rò pé, “Ta ló rí wa? Ta ni yóò mọ̀?” 16Ẹ̀yin dojú nǹkan délẹ̀, bí ẹni pé wọ́n rò pé amọ̀kòkò dàbí amọ̀! Ǹjẹ́ ohun tí a ṣe le sọ fún olùṣe pé, “Òun kọ́ ló ṣe mí”? Ǹjẹ́ ìkòkò lè sọ nípa amọ̀kòkò pé, “Kò mọ nǹkan”? 17Ní àìpẹ́ jọjọ, ǹjẹ́ a kò ní sọ Lebanoni di pápá ẹlẹ́tù lójú àti pápá ẹlẹ́tù lójú yóò dàbí aginjù? 18Ní ọjọ́ náà adití yóò gbọ́ ọ̀rọ̀ ìwé kíká náà, láti inú fìrífìrí àti òkùnkùn ni àwọn ojú afọ́jú yóò ríran. 19Lẹ́ẹ̀kan sí i àwọn onírẹ̀lẹ̀ yóò yọ̀ nínú Olúwa: àwọn aláìní yóò yọ̀ nínú Ẹni Mímọ́ ti Israẹli.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.