Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ẹ̀yin dojú nǹkan délẹ̀, bí ẹni pé wọ́n rò pé amọ̀kòkò dàbí amọ̀! Ǹjẹ́ ohun tí a ṣe le sọ fún olùṣe pé, “Òun kọ́ ló ṣe mí”? Ǹjẹ́ ìkòkò lè sọ nípa amọ̀kòkò pé, “Kò mọ nǹkan”?

Isaiah 29:16 in English

Isaiah 29:16 · Berean Standard Bible

You have turned things upside down, as if the potter were regarded as clay. Shall what is formed say to him who formed it, “He did not make me”?* Can the pottery say of the potter, “He has no understanding”?

Context

14Nítorí náà lẹ́ẹ̀kan sí i èmi yóò ya àwọn ènìyàn yìí lẹ́nu pẹ̀lú ìyanu lórí ìyanu; ọgbọ́n àwọn ọlọ́gbọ́n ni yóò ṣègbé, ìmọ̀ àwọn onímọ̀ ni yóò pòórá.” 15Ègbé ni fún àwọn tí ó lọ sí ọ̀gbun láti fi ètò wọn pamọ́ kúrò lójú Olúwa, tí wọ́n ń ṣe iṣẹ́ ẹ wọn nínú òkùnkùn tí wọ́n sì rò pé, “Ta ló rí wa? Ta ni yóò mọ̀?” 16Ẹ̀yin dojú nǹkan délẹ̀, bí ẹni pé wọ́n rò pé amọ̀kòkò dàbí amọ̀! Ǹjẹ́ ohun tí a ṣe le sọ fún olùṣe pé, “Òun kọ́ ló ṣe mí”? Ǹjẹ́ ìkòkò lè sọ nípa amọ̀kòkò pé, “Kò mọ nǹkan”? 17Ní àìpẹ́ jọjọ, ǹjẹ́ a kò ní sọ Lebanoni di pápá ẹlẹ́tù lójú àti pápá ẹlẹ́tù lójú yóò dàbí aginjù? 18Ní ọjọ́ náà adití yóò gbọ́ ọ̀rọ̀ ìwé kíká náà, láti inú fìrífìrí àti òkùnkùn ni àwọn ojú afọ́jú yóò ríran.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.