Isaiah 29:15
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ègbé ni fún àwọn tí ó lọ sí ọ̀gbun láti fi ètò wọn pamọ́ kúrò lójú Olúwa, tí wọ́n ń ṣe iṣẹ́ ẹ wọn nínú òkùnkùn tí wọ́n sì rò pé, “Ta ló rí wa? Ta ni yóò mọ̀?”
Isaiah 29:15 in English
Isaiah 29:15 · Berean Standard Bible
Woe to those who dig deep to hide their plans from the LORD. In darkness they do their works and say, “Who sees us, and who will know?”
Context
13Olúwa wí pé:
“Àwọn ènìyàn yìí súnmọ́ ọ̀dọ̀ mi pẹ̀lú ẹnu wọn,
wọ́n sì bọ̀wọ̀ fún mi pẹ̀lú ètè wọn,
ṣùgbọ́n ọkàn wọn jìnnà sí mi.
Ìsìn wọn si mi
ni a gbé ka orí òfin tí àwọn
ọkùnrin kọ́ ni. 14Nítorí náà lẹ́ẹ̀kan sí i èmi yóò ya
àwọn ènìyàn yìí lẹ́nu
pẹ̀lú ìyanu lórí ìyanu;
ọgbọ́n àwọn ọlọ́gbọ́n ni yóò ṣègbé,
ìmọ̀ àwọn onímọ̀ ni yóò pòórá.” 15Ègbé ni fún àwọn tí ó lọ sí ọ̀gbun
láti fi ètò wọn pamọ́ kúrò lójú Olúwa,
tí wọ́n ń ṣe iṣẹ́ ẹ wọn nínú òkùnkùn
tí wọ́n sì rò pé,
“Ta ló rí wa? Ta ni yóò mọ̀?” 16Ẹ̀yin dojú nǹkan délẹ̀,
bí ẹni pé wọ́n rò pé amọ̀kòkò dàbí amọ̀!
Ǹjẹ́ ohun tí a ṣe le sọ fún olùṣe pé,
“Òun kọ́ ló ṣe mí”?
Ǹjẹ́ ìkòkò lè sọ nípa amọ̀kòkò pé,
“Kò mọ nǹkan”? 17Ní àìpẹ́ jọjọ, ǹjẹ́
a kò ní sọ Lebanoni di pápá ẹlẹ́tù lójú
àti pápá ẹlẹ́tù lójú yóò dàbí aginjù?
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.