Isaiah 29:13
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Olúwa wí pé: “Àwọn ènìyàn yìí súnmọ́ ọ̀dọ̀ mi pẹ̀lú ẹnu wọn, wọ́n sì bọ̀wọ̀ fún mi pẹ̀lú ètè wọn, ṣùgbọ́n ọkàn wọn jìnnà sí mi. Ìsìn wọn si mi ni a gbé ka orí òfin tí àwọn ọkùnrin kọ́ ni.
Isaiah 29:13 in English
Isaiah 29:13 · Berean Standard Bible
Therefore the Lord said: “These people draw near to Me with their mouths and honor Me with their lips, but their hearts are far from Me. Their worship of Me is but rules taught by men.*
Context
11Fún un yín gbogbo ìran yìí kò yàtọ̀ sí àwọn ọ̀rọ̀ tí a fi èdìdì dì sínú ìwé kíká. Bí ẹ bá sì fún ẹni tí ó lè ka ìwé kíká náà, tí ẹ sì sọ fún un pé, “Jọ̀wọ́ ka èyí,” òun yóò dáhùn pé, “Èmi kò lè kà á; a ti dì í ní èdìdì.” 12Tàbí bí ẹ bá fún ẹni tí kò lè ka ìwé kíká náà tí ẹ sì sọ pé, “Jọ̀wọ́ ka èyí,” òun yóò dáhùn pé, “Èmi kò mọ̀ ọ́n kà.” 13Olúwa wí pé:
“Àwọn ènìyàn yìí súnmọ́ ọ̀dọ̀ mi pẹ̀lú ẹnu wọn,
wọ́n sì bọ̀wọ̀ fún mi pẹ̀lú ètè wọn,
ṣùgbọ́n ọkàn wọn jìnnà sí mi.
Ìsìn wọn si mi
ni a gbé ka orí òfin tí àwọn
ọkùnrin kọ́ ni. 14Nítorí náà lẹ́ẹ̀kan sí i èmi yóò ya
àwọn ènìyàn yìí lẹ́nu
pẹ̀lú ìyanu lórí ìyanu;
ọgbọ́n àwọn ọlọ́gbọ́n ni yóò ṣègbé,
ìmọ̀ àwọn onímọ̀ ni yóò pòórá.” 15Ègbé ni fún àwọn tí ó lọ sí ọ̀gbun
láti fi ètò wọn pamọ́ kúrò lójú Olúwa,
tí wọ́n ń ṣe iṣẹ́ ẹ wọn nínú òkùnkùn
tí wọ́n sì rò pé,
“Ta ló rí wa? Ta ni yóò mọ̀?”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.