Isaiah 29:19
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Lẹ́ẹ̀kan sí i àwọn onírẹ̀lẹ̀ yóò yọ̀ nínú Olúwa: àwọn aláìní yóò yọ̀ nínú Ẹni Mímọ́ ti Israẹli.
Isaiah 29:19 in English
Isaiah 29:19 · Berean Standard Bible
The humble will increase their joy in the LORD, and the poor among men will rejoice in the Holy One of Israel.
Context
17Ní àìpẹ́ jọjọ, ǹjẹ́
a kò ní sọ Lebanoni di pápá ẹlẹ́tù lójú
àti pápá ẹlẹ́tù lójú yóò dàbí aginjù? 18Ní ọjọ́ náà adití yóò gbọ́ ọ̀rọ̀ ìwé kíká náà,
láti inú fìrífìrí àti òkùnkùn
ni àwọn ojú afọ́jú yóò ríran. 19Lẹ́ẹ̀kan sí i àwọn onírẹ̀lẹ̀ yóò yọ̀ nínú Olúwa:
àwọn aláìní yóò yọ̀ nínú Ẹni Mímọ́ ti Israẹli. 20Aláìláàánú yóò pòórá,
àwọn tí ń ṣẹlẹ́yà yóò di àwátì,
gbogbo àwọn tí ó ní ojú ibi ni a ó ké lulẹ̀— 21àwọn tí wọ́n fi ọ̀rọ̀ kan mú ẹnìkan di ẹlẹ́bi,
ẹni tí ń dẹkùn mú olùgbèjà ní ilé ẹjọ́
tí ẹ fi ẹ̀rí èké dun aláìṣẹ̀ ní ìdájọ́.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.