Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

àwọn tí wọ́n fi ọ̀rọ̀ kan mú ẹnìkan di ẹlẹ́bi, ẹni tí ń dẹkùn mú olùgbèjà ní ilé ẹjọ́ tí ẹ fi ẹ̀rí èké dun aláìṣẹ̀ ní ìdájọ́.

Isaiah 29:21 in English

Isaiah 29:21 · Berean Standard Bible

those who indict a man with a word, who ensnare the mediator at the gate, and who with false charges deprive the innocent of justice.

Context

19Lẹ́ẹ̀kan sí i àwọn onírẹ̀lẹ̀ yóò yọ̀ nínú Olúwa: àwọn aláìní yóò yọ̀ nínú Ẹni Mímọ́ ti Israẹli. 20Aláìláàánú yóò pòórá, àwọn tí ń ṣẹlẹ́yà yóò di àwátì, gbogbo àwọn tí ó ní ojú ibi ni a ó ké lulẹ̀— 21àwọn tí wọ́n fi ọ̀rọ̀ kan mú ẹnìkan di ẹlẹ́bi, ẹni tí ń dẹkùn mú olùgbèjà ní ilé ẹjọ́ tí ẹ fi ẹ̀rí èké dun aláìṣẹ̀ ní ìdájọ́. 22Nítorí náà, èyí ni ohun tí Olúwa, ẹni tí ó ra Abrahamu padà sọ sí ilé Jakọbu: “Ojú kì yóò ti Jakọbu mọ́; ojú wọn kì yóò sì rẹ̀wẹ̀sì mọ́. 23Nígbà tí wọ́n bá rí i láàrín àwọn ọmọ wọn, àwọn iṣẹ́ ọwọ́ mi, wọn yóò ya orúkọ mi sí mímọ́, wọn yóò tẹ́wọ́gbà mímọ́ Ẹni Mímọ́ Jakọbu wọn yóò dìde dúró ní ìbọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run Israẹli.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.