Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nítorí náà, èyí ni ohun tí Olúwa, ẹni tí ó ra Abrahamu padà sọ sí ilé Jakọbu: “Ojú kì yóò ti Jakọbu mọ́; ojú wọn kì yóò sì rẹ̀wẹ̀sì mọ́.

Isaiah 29:22 in English

Isaiah 29:22 · Berean Standard Bible

Therefore the LORD who redeemed Abraham says of the house of Jacob: “No longer will Jacob be ashamed and no more will his face grow pale.

Context

20Aláìláàánú yóò pòórá, àwọn tí ń ṣẹlẹ́yà yóò di àwátì, gbogbo àwọn tí ó ní ojú ibi ni a ó ké lulẹ̀— 21àwọn tí wọ́n fi ọ̀rọ̀ kan mú ẹnìkan di ẹlẹ́bi, ẹni tí ń dẹkùn mú olùgbèjà ní ilé ẹjọ́ tí ẹ fi ẹ̀rí èké dun aláìṣẹ̀ ní ìdájọ́. 22Nítorí náà, èyí ni ohun tí Olúwa, ẹni tí ó ra Abrahamu padà sọ sí ilé Jakọbu: “Ojú kì yóò ti Jakọbu mọ́; ojú wọn kì yóò sì rẹ̀wẹ̀sì mọ́. 23Nígbà tí wọ́n bá rí i láàrín àwọn ọmọ wọn, àwọn iṣẹ́ ọwọ́ mi, wọn yóò ya orúkọ mi sí mímọ́, wọn yóò tẹ́wọ́gbà mímọ́ Ẹni Mímọ́ Jakọbu wọn yóò dìde dúró ní ìbọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run Israẹli. 24Gbogbo àwọn tí ń rìn ségesège ní yóò jèrè ìmọ̀; gbogbo àwọn tí ń ṣe àròyé yóò gba ìtọ́sọ́nà.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.