Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Olúwa ti na ọwọ́ rẹ̀ jáde sí orí Òkun ó sì mú kí àwọn ilẹ̀ ọba wárìrì. Ó ti pa àṣẹ kan tí ó kan Kenaani pé kí a pa ilé ààbò rẹ̀ run.

Isaiah 23:11 in English

Isaiah 23:11 · Berean Standard Bible

The LORD has stretched out His hand over the sea; He has made kingdoms tremble. He has given a command that the strongholds of Canaan be destroyed.

Context

9Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti ṣètò rẹ̀, láti tẹrí ìgbéraga àti ògo rẹ ba àti láti rẹ gbogbo àwọn ọlọ́lá ilé ayé sílẹ̀. 10Tu ilẹ̀ rẹ gẹ́gẹ́ bí i ti ipadò odò Ejibiti, ìwọ ọmọbìnrin Tarṣiṣi, nítorí ìwọ kò ní èbúté mọ́. 11Olúwa ti na ọwọ́ rẹ̀ jáde sí orí Òkun ó sì mú kí àwọn ilẹ̀ ọba wárìrì. Ó ti pa àṣẹ kan tí ó kan Kenaani pé kí a pa ilé ààbò rẹ̀ run. 12Ó wí pé, “Kò sí àríyá fún ọ mọ́, ìwọ wúńdíá ti Sidoni, tí a ti tẹ̀ mọ́lẹ̀ báyìí! “Gbéra, rékọjá lọ sí Saipurọsi, níbẹ̀ pẹ̀lú o kì yóò ní ìsinmi.” 13Bojú wo ilẹ̀ àwọn ará Babeli, àwọn ènìyàn tí kò jámọ́ nǹkan kan báyìí. Àwọn Asiria ti sọ ọ́ di ibùgbé àwọn ohun ẹranko aginjù; wọn ti gbé ilé ìṣọ́ ìtẹ̀gùn wọn sókè, wọ́n ti tú odi rẹ̀ sí ìhòhò wọ́n sì ti sọ ọ́ di ààtàn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.