Isaiah 23:13
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Bojú wo ilẹ̀ àwọn ará Babeli, àwọn ènìyàn tí kò jámọ́ nǹkan kan báyìí. Àwọn Asiria ti sọ ọ́ di ibùgbé àwọn ohun ẹranko aginjù; wọn ti gbé ilé ìṣọ́ ìtẹ̀gùn wọn sókè, wọ́n ti tú odi rẹ̀ sí ìhòhò wọ́n sì ti sọ ọ́ di ààtàn.
Isaiah 23:13 in English
Isaiah 23:13 · Berean Standard Bible
Look at the land of the Chaldeans *— a people now of no account. The Assyrians destined it for the desert creatures; they set up their siege towers and stripped its palaces. They brought it to ruin.
Context
11Olúwa ti na ọwọ́ rẹ̀ jáde sí orí Òkun
ó sì mú kí àwọn ilẹ̀ ọba wárìrì.
Ó ti pa àṣẹ kan tí ó kan Kenaani
pé kí a pa ilé ààbò rẹ̀ run. 12Ó wí pé, “Kò sí àríyá fún ọ mọ́,
ìwọ wúńdíá ti Sidoni, tí a ti tẹ̀ mọ́lẹ̀ báyìí!
“Gbéra, rékọjá lọ sí Saipurọsi,
níbẹ̀ pẹ̀lú o kì yóò ní ìsinmi.” 13Bojú wo ilẹ̀ àwọn ará Babeli,
àwọn ènìyàn tí kò jámọ́ nǹkan kan báyìí.
Àwọn Asiria ti sọ ọ́ di
ibùgbé àwọn ohun ẹranko aginjù;
wọn ti gbé ilé ìṣọ́ ìtẹ̀gùn wọn sókè,
wọ́n ti tú odi rẹ̀ sí ìhòhò
wọ́n sì ti sọ ọ́ di ààtàn. 14Hu, ìwọ ọkọ̀ ojú omi Tarṣiṣi;
wọ́n ti pa odi rẹ̀ run! 15Ní àkókò náà a ó gbàgbé Tire fún àádọ́rin ọdún, ọjọ́ ayé ọba kan. Ṣùgbọ́n ní òpin àádọ́rin ọdún wọ̀nyí, yóò ṣẹlẹ̀ sí Tire gẹ́gẹ́ bí orin àgbèrè:
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.