Isaiah 23:15
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ní àkókò náà a ó gbàgbé Tire fún àádọ́rin ọdún, ọjọ́ ayé ọba kan. Ṣùgbọ́n ní òpin àádọ́rin ọdún wọ̀nyí, yóò ṣẹlẹ̀ sí Tire gẹ́gẹ́ bí orin àgbèrè:
Isaiah 23:15 in English
Isaiah 23:15 · Berean Standard Bible
At that time Tyre will be forgotten for seventy years—the span of a king’s life. But at the end of seventy years, it will happen to Tyre as in the song of the harlot:
Context
13Bojú wo ilẹ̀ àwọn ará Babeli,
àwọn ènìyàn tí kò jámọ́ nǹkan kan báyìí.
Àwọn Asiria ti sọ ọ́ di
ibùgbé àwọn ohun ẹranko aginjù;
wọn ti gbé ilé ìṣọ́ ìtẹ̀gùn wọn sókè,
wọ́n ti tú odi rẹ̀ sí ìhòhò
wọ́n sì ti sọ ọ́ di ààtàn. 14Hu, ìwọ ọkọ̀ ojú omi Tarṣiṣi;
wọ́n ti pa odi rẹ̀ run! 15Ní àkókò náà a ó gbàgbé Tire fún àádọ́rin ọdún, ọjọ́ ayé ọba kan. Ṣùgbọ́n ní òpin àádọ́rin ọdún wọ̀nyí, yóò ṣẹlẹ̀ sí Tire gẹ́gẹ́ bí orin àgbèrè: 16“Mú dùùrù kan, rìn kọjá láàrín ìlú,
ìwọ àgbèrè tí a ti gbàgbé;
lu dùùrù dáradára, kọ ọ̀pọ̀ orin,
kí a lè ba à rántí rẹ.” 17Ní òpin àádọ́rin ọdún náà, Olúwa yóò bá Tire jà. Òun yóò sì padà sí àyálò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí panṣágà, yóò sì máa ṣe òwò rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ilẹ̀ ọba tí ó wà ní ilẹ̀ ayé.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.