Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Mú dùùrù kan, rìn kọjá láàrín ìlú, ìwọ àgbèrè tí a ti gbàgbé; lu dùùrù dáradára, kọ ọ̀pọ̀ orin, kí a lè ba à rántí rẹ.”

Isaiah 23:16 in English

Isaiah 23:16 · Berean Standard Bible

“Take up your harp, stroll through the city, O forgotten harlot. Make sweet melody, sing many a song, so you will be remembered.”

Context

14Hu, ìwọ ọkọ̀ ojú omi Tarṣiṣi; wọ́n ti pa odi rẹ̀ run! 15Ní àkókò náà a ó gbàgbé Tire fún àádọ́rin ọdún, ọjọ́ ayé ọba kan. Ṣùgbọ́n ní òpin àádọ́rin ọdún wọ̀nyí, yóò ṣẹlẹ̀ sí Tire gẹ́gẹ́ bí orin àgbèrè: 16“Mú dùùrù kan, rìn kọjá láàrín ìlú, ìwọ àgbèrè tí a ti gbàgbé; lu dùùrù dáradára, kọ ọ̀pọ̀ orin, kí a lè ba à rántí rẹ.” 17Ní òpin àádọ́rin ọdún náà, Olúwa yóò bá Tire jà. Òun yóò sì padà sí àyálò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí panṣágà, yóò sì máa ṣe òwò rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ilẹ̀ ọba tí ó wà ní ilẹ̀ ayé. 18Síbẹ̀síbẹ̀ èrè rẹ̀ àti owó iṣẹ́ rẹ̀ ni a ó yà sọ́tọ̀ fún Olúwa; a kò ní kó wọn pamọ́ tàbí kí a há wọn mọ́wọ́. Ère rẹ̀ ni a ó fi fún àwọn tí ó ń gbé níwájú Olúwa, fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ oúnjẹ àti aṣọ.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.