Isaiah 23:12
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ó wí pé, “Kò sí àríyá fún ọ mọ́, ìwọ wúńdíá ti Sidoni, tí a ti tẹ̀ mọ́lẹ̀ báyìí! “Gbéra, rékọjá lọ sí Saipurọsi, níbẹ̀ pẹ̀lú o kì yóò ní ìsinmi.”
Isaiah 23:12 in English
Isaiah 23:12 · Berean Standard Bible
He said, “You shall rejoice no more, O oppressed Virgin Daughter of Sidon. Get up and cross over to Cyprus— even there you will find no rest.”
Context
10Tu ilẹ̀ rẹ gẹ́gẹ́ bí i ti ipadò odò Ejibiti,
ìwọ ọmọbìnrin Tarṣiṣi,
nítorí ìwọ kò ní èbúté mọ́. 11Olúwa ti na ọwọ́ rẹ̀ jáde sí orí Òkun
ó sì mú kí àwọn ilẹ̀ ọba wárìrì.
Ó ti pa àṣẹ kan tí ó kan Kenaani
pé kí a pa ilé ààbò rẹ̀ run. 12Ó wí pé, “Kò sí àríyá fún ọ mọ́,
ìwọ wúńdíá ti Sidoni, tí a ti tẹ̀ mọ́lẹ̀ báyìí!
“Gbéra, rékọjá lọ sí Saipurọsi,
níbẹ̀ pẹ̀lú o kì yóò ní ìsinmi.” 13Bojú wo ilẹ̀ àwọn ará Babeli,
àwọn ènìyàn tí kò jámọ́ nǹkan kan báyìí.
Àwọn Asiria ti sọ ọ́ di
ibùgbé àwọn ohun ẹranko aginjù;
wọn ti gbé ilé ìṣọ́ ìtẹ̀gùn wọn sókè,
wọ́n ti tú odi rẹ̀ sí ìhòhò
wọ́n sì ti sọ ọ́ di ààtàn. 14Hu, ìwọ ọkọ̀ ojú omi Tarṣiṣi;
wọ́n ti pa odi rẹ̀ run!
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.