Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Èyí ni ètò tí a pinnu rẹ̀ fún gbogbo ayé, èyí ni ọwọ́ tí a nà jáde káàkiri gbogbo orílẹ̀-èdè.

Isaiah 14:26 in English

Isaiah 14:26 · Berean Standard Bible

This is the plan devised for the whole earth, and this is the hand stretched out over all the nations.

Context

24Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti búra, “Gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣètò, bẹ́ẹ̀ ni yóò rí, àti bí mo ti pinnu, bẹ́ẹ̀ ni yóò sì dúró. 25Èmi yóò run Asiria ní ilẹ̀ mi, ní àwọn orí òkè mi ni èmi yóò ti rún un mọ́lẹ̀. Àjàgà rẹ̀ ni a ó mú kúrò lọ́rùn àwọn ènìyàn mi, ẹrù u rẹ̀ ni ó mú kúrò ní èjìká wọn.” 26Èyí ni ètò tí a pinnu rẹ̀ fún gbogbo ayé, èyí ni ọwọ́ tí a nà jáde káàkiri gbogbo orílẹ̀-èdè. 27Nítorí Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti pète, ta ni yóò sì ká a lọ́wọ́ kò? Ọwọ́ọ rẹ ti nà jáde, ta ni ó sì le è fà á padà? 28Ọ̀rọ̀-ìmọ̀ yí wá ní ọdún tí ọba Ahasi kú.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.