Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ọ̀rọ̀-ìmọ̀ yí wá ní ọdún tí ọba Ahasi kú.

Isaiah 14:28 in English

Isaiah 14:28 · Berean Standard Bible

In the year that King Ahaz died, this burden was received:

Context

26Èyí ni ètò tí a pinnu rẹ̀ fún gbogbo ayé, èyí ni ọwọ́ tí a nà jáde káàkiri gbogbo orílẹ̀-èdè. 27Nítorí Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti pète, ta ni yóò sì ká a lọ́wọ́ kò? Ọwọ́ọ rẹ ti nà jáde, ta ni ó sì le è fà á padà? 28Ọ̀rọ̀-ìmọ̀ yí wá ní ọdún tí ọba Ahasi kú. 29Má ṣe yọ̀, gbogbo ẹ̀yin Filistia, pé ọ̀pá tí ó lù ọ́ ti dá; láti ibi gbòǹgbò ejò náà ni paramọ́lẹ̀ yóò ti hù jáde, èso rẹ̀ yóò sì jẹ́ oró ejò tí í jóni. 30Ẹni tí ó kúṣẹ̀ẹ́ jù yóò ní pápá oko, àwọn aláìní yóò sì dùbúlẹ̀ láìléwu. Ṣùgbọ́n gbòǹgbò o rẹ̀ ni èmi ó fi ìyàn parun, yóò sì ké àwọn ẹni rẹ tí ó sálà kúrò.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.