Isaiah 14:29
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Má ṣe yọ̀, gbogbo ẹ̀yin Filistia, pé ọ̀pá tí ó lù ọ́ ti dá; láti ibi gbòǹgbò ejò náà ni paramọ́lẹ̀ yóò ti hù jáde, èso rẹ̀ yóò sì jẹ́ oró ejò tí í jóni.
Isaiah 14:29 in English
Isaiah 14:29 · Berean Standard Bible
Do not rejoice, all you Philistines, that the rod that struck you is broken. For a viper will spring from the root of the snake, and a flying serpent from its egg.
Context
27Nítorí Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti pète,
ta ni yóò sì ká a lọ́wọ́ kò?
Ọwọ́ọ rẹ ti nà jáde, ta ni ó sì le è fà á padà? 28Ọ̀rọ̀-ìmọ̀ yí wá ní ọdún tí ọba Ahasi kú. 29Má ṣe yọ̀, gbogbo ẹ̀yin Filistia,
pé ọ̀pá tí ó lù ọ́ ti dá;
láti ibi gbòǹgbò ejò náà ni paramọ́lẹ̀
yóò ti hù jáde,
èso rẹ̀ yóò sì jẹ́ oró ejò tí í jóni. 30Ẹni tí ó kúṣẹ̀ẹ́ jù yóò ní pápá oko,
àwọn aláìní yóò sì dùbúlẹ̀ láìléwu.
Ṣùgbọ́n gbòǹgbò o rẹ̀ ni èmi ó fi ìyàn parun,
yóò sì ké àwọn ẹni rẹ tí ó sálà kúrò. 31Hu, ìwọ ẹnu-ọ̀nà! Kígbe, ìwọ ìlú!
Yọ́ kúrò, gbogbo ẹ̀yin Filistia!
Èéfín kurukuru kan ti àríwá wá,
kò sì ṣí amóríbọ́ kan nínú ẹgbẹ́ wọn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.