Isaiah 14:25
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Èmi yóò run Asiria ní ilẹ̀ mi, ní àwọn orí òkè mi ni èmi yóò ti rún un mọ́lẹ̀. Àjàgà rẹ̀ ni a ó mú kúrò lọ́rùn àwọn ènìyàn mi, ẹrù u rẹ̀ ni ó mú kúrò ní èjìká wọn.”
Isaiah 14:25 in English
Isaiah 14:25 · Berean Standard Bible
I will break Assyria in My land; I will trample him on My mountain. His yoke will be taken off My people, and his burden removed from their shoulders.”
Context
23Èmi yóò yí i padà sí ibùgbé àwọn òwìwí
àti sí irà;
Èmi yóò fi ọwọ́ ìparun gbá a,
ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí. 24Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti búra,
“Gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣètò, bẹ́ẹ̀ ni yóò rí,
àti bí mo ti pinnu, bẹ́ẹ̀ ni yóò sì dúró. 25Èmi yóò run Asiria ní ilẹ̀ mi,
ní àwọn orí òkè mi ni èmi yóò ti rún un mọ́lẹ̀.
Àjàgà rẹ̀ ni a ó mú kúrò lọ́rùn àwọn ènìyàn mi,
ẹrù u rẹ̀ ni ó mú kúrò ní èjìká wọn.” 26Èyí ni ètò tí a pinnu rẹ̀ fún gbogbo ayé,
èyí ni ọwọ́ tí a nà jáde káàkiri gbogbo orílẹ̀-èdè. 27Nítorí Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti pète,
ta ni yóò sì ká a lọ́wọ́ kò?
Ọwọ́ọ rẹ ti nà jáde, ta ni ó sì le è fà á padà?
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.