Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ẹni tí ó sọ ayé di aginjù, tí ó sì pa ìlú ńlá ńlá rẹ̀ run tí kò dá àwọn òǹdè rẹ̀ sílẹ̀ láti padà sílé?”

Isaiah 14:17 in English

Isaiah 14:17 · Berean Standard Bible

who turned the world into a desert and destroyed its cities, who refused to let the captives return to their homes?”

Context

15Ṣùgbọ́n a ti rẹ̀ ọ́ sílẹ̀ wọ inú ibojì lọ lọ sí ìsàlẹ̀ ọ̀gbun. 16Àwọn tí ó rí ọ yóò tẹjúmọ́ ọ, wọ́n ronú nípa àtubọ̀tán rẹ: “Ǹjẹ́ èyí ni ẹni tí ó mi ayé tìtì tí ó sì jẹ́ kí àwọn ilẹ̀ ọba wárìrì. 17Ẹni tí ó sọ ayé di aginjù, tí ó sì pa ìlú ńlá ńlá rẹ̀ run tí kò dá àwọn òǹdè rẹ̀ sílẹ̀ láti padà sílé?” 18Gbogbo àwọn ọba orílẹ̀-èdè ni a tẹ́ sílẹ̀ ọ̀kọ̀ọ̀kan nínú ibojì tirẹ̀. 19Ṣùgbọ́n a jù ọ́ síta kúrò nínú ibojì gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ka igi tí a kọ̀sílẹ̀, àwọn tí a pa ni ó bò ọ́ mọ́lẹ̀, àwọn tí idà ti gún, àwọn tí ó sọ̀kalẹ̀ lọ sínú òkúta inú ọ̀gbun. Gẹ́gẹ́ bí òkú ó di ìtẹ̀mọ́lẹ̀ ní abẹ́ àtẹ́lẹsẹ̀,

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.