Isaiah 14:18
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Gbogbo àwọn ọba orílẹ̀-èdè ni a tẹ́ sílẹ̀ ọ̀kọ̀ọ̀kan nínú ibojì tirẹ̀.
Isaiah 14:18 in English
Isaiah 14:18 · Berean Standard Bible
All the kings of the nations lie in state, each in his own tomb.*
Context
16Àwọn tí ó rí ọ yóò tẹjúmọ́ ọ,
wọ́n ronú nípa àtubọ̀tán rẹ:
“Ǹjẹ́ èyí ni ẹni tí ó mi ayé tìtì
tí ó sì jẹ́ kí àwọn ilẹ̀ ọba wárìrì. 17Ẹni tí ó sọ ayé di aginjù,
tí ó sì pa ìlú ńlá ńlá rẹ̀ run
tí kò dá àwọn òǹdè rẹ̀ sílẹ̀ láti padà sílé?” 18Gbogbo àwọn ọba orílẹ̀-èdè ni a tẹ́ sílẹ̀
ọ̀kọ̀ọ̀kan nínú ibojì tirẹ̀. 19Ṣùgbọ́n a jù ọ́ síta kúrò nínú ibojì
gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ka igi tí a kọ̀sílẹ̀,
àwọn tí a pa ni ó bò ọ́ mọ́lẹ̀,
àwọn tí idà ti gún,
àwọn tí ó sọ̀kalẹ̀ lọ sínú òkúta inú ọ̀gbun.
Gẹ́gẹ́ bí òkú ó di ìtẹ̀mọ́lẹ̀ ní abẹ́ àtẹ́lẹsẹ̀, 20a kò ní sin ọ́ pẹ̀lú wọn,
nítorí pé o ti ba ilẹ̀ rẹ jẹ́
o sì ti pa àwọn ènìyàn rẹ.
Ìran àwọn ìkà
ni a kì yóò dárúkọ wọn mọ́.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.