Isaiah 14:16
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àwọn tí ó rí ọ yóò tẹjúmọ́ ọ, wọ́n ronú nípa àtubọ̀tán rẹ: “Ǹjẹ́ èyí ni ẹni tí ó mi ayé tìtì tí ó sì jẹ́ kí àwọn ilẹ̀ ọba wárìrì.
Isaiah 14:16 in English
Isaiah 14:16 · Berean Standard Bible
Those who see you will stare; they will ponder your fate: “Is this the man who shook the earth and made the kingdoms tremble,
Context
14Èmi yóò gòkè lọ rékọjá àwọn àwọsánmọ̀;
èmi yóò ṣe ara mi gẹ́gẹ́ bí Ọ̀gá-ògo.” 15Ṣùgbọ́n a ti rẹ̀ ọ́ sílẹ̀ wọ inú ibojì lọ
lọ sí ìsàlẹ̀ ọ̀gbun. 16Àwọn tí ó rí ọ yóò tẹjúmọ́ ọ,
wọ́n ronú nípa àtubọ̀tán rẹ:
“Ǹjẹ́ èyí ni ẹni tí ó mi ayé tìtì
tí ó sì jẹ́ kí àwọn ilẹ̀ ọba wárìrì. 17Ẹni tí ó sọ ayé di aginjù,
tí ó sì pa ìlú ńlá ńlá rẹ̀ run
tí kò dá àwọn òǹdè rẹ̀ sílẹ̀ láti padà sílé?” 18Gbogbo àwọn ọba orílẹ̀-èdè ni a tẹ́ sílẹ̀
ọ̀kọ̀ọ̀kan nínú ibojì tirẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.