Isaiah 14:10
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Gbogbo wọn yóò dáhùn, wọn yóò wí fún ọ wí pé, “Ìwọ pẹ̀lú ti di aláìlera, gẹ́gẹ́ bí àwa pẹ̀lú ìwọ náà ti dàbí wa.”
Isaiah 14:10 in English
Isaiah 14:10 · Berean Standard Bible
They will all respond to you, saying, “You too have become weak, as we are; you have become like us!”
Context
8Pẹ̀lúpẹ̀lú àwọn igi junifa àti àwọn
igi kedari ti Lebanoni
ń yọ̀ lórí rẹ wí pé,
“Níwọ́n bí a ti rẹ̀ ọ́ sílẹ̀ báyìí,
kò sí agégi tí yóò wá láti gé wa lulẹ̀.” 9Ibojì tí ó wà ní ìsàlẹ̀ ni a ru sókè
láti pàdé rẹ ní ìpadàbọ̀ rẹ̀
ó ru ẹ̀mí àwọn tí ó ti lọ sókè láti wá kí ọ
gbogbo àwọn tí ó jẹ́ olórí ní ayé
ó mú kí wọn dìde lórí ìtẹ́ wọn
gbogbo àwọn tí ó jẹ ọba lórí àwọn orílẹ̀-èdè. 10Gbogbo wọn yóò dáhùn,
wọn yóò wí fún ọ wí pé,
“Ìwọ pẹ̀lú ti di aláìlera, gẹ́gẹ́ bí àwa pẹ̀lú
ìwọ náà ti dàbí wa.” 11Gbogbo rẹ̀ ni ó di ìrẹ̀sílẹ̀ lọ sí ibojì,
pẹ̀lú ariwo àwọn dùùrù rẹ,
àwọn ìdin ni wọ́n fọ́nkálẹ̀ lábẹ́ rẹ
àwọn ekòló sì ti bò ọ́ mọ́lẹ̀. 12Báwo ni ìwọ ṣe ṣubú lulẹ̀ láti ọ̀run wá,
ìwọ ìràwọ̀ òwúrọ̀, ọmọ òwúrọ̀ náà!
A ti sọ ọ́ sílẹ̀ sínú ayé,
ìwọ tí o ti tẹ orí àwọn orílẹ̀-èdè ba rí!
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.