Isaiah 14:9
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ibojì tí ó wà ní ìsàlẹ̀ ni a ru sókè láti pàdé rẹ ní ìpadàbọ̀ rẹ̀ ó ru ẹ̀mí àwọn tí ó ti lọ sókè láti wá kí ọ gbogbo àwọn tí ó jẹ́ olórí ní ayé ó mú kí wọn dìde lórí ìtẹ́ wọn gbogbo àwọn tí ó jẹ ọba lórí àwọn orílẹ̀-èdè.
Isaiah 14:9 in English
Isaiah 14:9 · Berean Standard Bible
Sheol beneath is eager to meet you upon your arrival. It stirs the spirits of the dead to greet you— all the rulers of the earth. It makes all the kings of the nations rise from their thrones.
Context
7Gbogbo ilẹ̀ ni ó wà ní ìsinmi àti àlàáfíà,
wọ́n bú sí orin. 8Pẹ̀lúpẹ̀lú àwọn igi junifa àti àwọn
igi kedari ti Lebanoni
ń yọ̀ lórí rẹ wí pé,
“Níwọ́n bí a ti rẹ̀ ọ́ sílẹ̀ báyìí,
kò sí agégi tí yóò wá láti gé wa lulẹ̀.” 9Ibojì tí ó wà ní ìsàlẹ̀ ni a ru sókè
láti pàdé rẹ ní ìpadàbọ̀ rẹ̀
ó ru ẹ̀mí àwọn tí ó ti lọ sókè láti wá kí ọ
gbogbo àwọn tí ó jẹ́ olórí ní ayé
ó mú kí wọn dìde lórí ìtẹ́ wọn
gbogbo àwọn tí ó jẹ ọba lórí àwọn orílẹ̀-èdè. 10Gbogbo wọn yóò dáhùn,
wọn yóò wí fún ọ wí pé,
“Ìwọ pẹ̀lú ti di aláìlera, gẹ́gẹ́ bí àwa pẹ̀lú
ìwọ náà ti dàbí wa.” 11Gbogbo rẹ̀ ni ó di ìrẹ̀sílẹ̀ lọ sí ibojì,
pẹ̀lú ariwo àwọn dùùrù rẹ,
àwọn ìdin ni wọ́n fọ́nkálẹ̀ lábẹ́ rẹ
àwọn ekòló sì ti bò ọ́ mọ́lẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.