Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Gbogbo rẹ̀ ni ó di ìrẹ̀sílẹ̀ lọ sí ibojì, pẹ̀lú ariwo àwọn dùùrù rẹ, àwọn ìdin ni wọ́n fọ́nkálẹ̀ lábẹ́ rẹ àwọn ekòló sì ti bò ọ́ mọ́lẹ̀.

Isaiah 14:11 in English

Isaiah 14:11 · Berean Standard Bible

Your pomp has been brought down to Sheol, along with the music of your harps. Maggots are your bed and worms your blanket.

Context

9Ibojì tí ó wà ní ìsàlẹ̀ ni a ru sókè láti pàdé rẹ ní ìpadàbọ̀ rẹ̀ ó ru ẹ̀mí àwọn tí ó ti lọ sókè láti wá kí ọ gbogbo àwọn tí ó jẹ́ olórí ní ayé ó mú kí wọn dìde lórí ìtẹ́ wọn gbogbo àwọn tí ó jẹ ọba lórí àwọn orílẹ̀-èdè. 10Gbogbo wọn yóò dáhùn, wọn yóò wí fún ọ wí pé, “Ìwọ pẹ̀lú ti di aláìlera, gẹ́gẹ́ bí àwa pẹ̀lú ìwọ náà ti dàbí wa.” 11Gbogbo rẹ̀ ni ó di ìrẹ̀sílẹ̀ lọ sí ibojì, pẹ̀lú ariwo àwọn dùùrù rẹ, àwọn ìdin ni wọ́n fọ́nkálẹ̀ lábẹ́ rẹ àwọn ekòló sì ti bò ọ́ mọ́lẹ̀. 12Báwo ni ìwọ ṣe ṣubú lulẹ̀ láti ọ̀run wá, ìwọ ìràwọ̀ òwúrọ̀, ọmọ òwúrọ̀ náà! A ti sọ ọ́ sílẹ̀ sínú ayé, ìwọ tí o ti tẹ orí àwọn orílẹ̀-èdè ba rí! 13Ìwọ sọ nínú ọkàn rẹ pé, “Èmi yóò gòkè lọ sí ọ̀run; èmi yóò gbé ìtẹ́ mi sókè ga ju àwọn ìràwọ̀ Ọlọ́run, Èmi yóò gúnwà ní orí òkè àpéjọ ní ṣóńṣó orí òkè mímọ́.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.