Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Pẹ̀lúpẹ̀lú àwọn igi junifa àti àwọn igi kedari ti Lebanoni ń yọ̀ lórí rẹ wí pé, “Níwọ́n bí a ti rẹ̀ ọ́ sílẹ̀ báyìí, kò sí agégi tí yóò wá láti gé wa lulẹ̀.”

Isaiah 14:8 in English

Isaiah 14:8 · Berean Standard Bible

Even the cypresses * and cedars of Lebanon exult over you: “Since you have been laid low, no woodcutter comes against us.”

Context

6èyí tí ó ti lu àwọn ènìyàn bolẹ̀ pẹ̀lú ti kò dáwọ́ dúró, nínú ìrunú ni ó ṣẹ́gun àwọn orílẹ̀-èdè pẹ̀lú ìgbónára tí kò lópin. 7Gbogbo ilẹ̀ ni ó wà ní ìsinmi àti àlàáfíà, wọ́n bú sí orin. 8Pẹ̀lúpẹ̀lú àwọn igi junifa àti àwọn igi kedari ti Lebanoni ń yọ̀ lórí rẹ wí pé, “Níwọ́n bí a ti rẹ̀ ọ́ sílẹ̀ báyìí, kò sí agégi tí yóò wá láti gé wa lulẹ̀.” 9Ibojì tí ó wà ní ìsàlẹ̀ ni a ru sókè láti pàdé rẹ ní ìpadàbọ̀ rẹ̀ ó ru ẹ̀mí àwọn tí ó ti lọ sókè láti wá kí ọ gbogbo àwọn tí ó jẹ́ olórí ní ayé ó mú kí wọn dìde lórí ìtẹ́ wọn gbogbo àwọn tí ó jẹ ọba lórí àwọn orílẹ̀-èdè. 10Gbogbo wọn yóò dáhùn, wọn yóò wí fún ọ wí pé, “Ìwọ pẹ̀lú ti di aláìlera, gẹ́gẹ́ bí àwa pẹ̀lú ìwọ náà ti dàbí wa.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.