Isaiah 11:10
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ní ọjọ́ náà, gbòǹgbò Jese yóò dúró gẹ́gẹ́ bí àsíá fún gbogbo ènìyàn, àwọn orílẹ̀-èdè yóò pagbo yí i ká, ibùdó ìsinmi rẹ̀ yóò jẹ́ èyí tí ó lógo.
Isaiah 11:10 in English
Isaiah 11:10 · Berean Standard Bible
On that day the Root of Jesse will stand as a banner for the peoples. The nations will seek Him,* and His place of rest will be glorious.
Context
8Ọ̀dọ́mọdé yóò ṣeré lẹ́bàá ihò ọká,
ọmọdé yóò ki ọwọ́ rẹ̀ bọ ìtẹ́ paramọ́lẹ̀. 9Wọn kò ní ṣe ni léṣe tàbí pa ni run
ní gbogbo òkè mímọ́ mi,
nítorí gbogbo ayé yóò kún fún ìmọ̀ Olúwa
gẹ́gẹ́ bí omi ti bo Òkun. 10Ní ọjọ́ náà, gbòǹgbò Jese yóò dúró gẹ́gẹ́ bí àsíá fún gbogbo ènìyàn, àwọn orílẹ̀-èdè yóò pagbo yí i ká, ibùdó ìsinmi rẹ̀ yóò jẹ́ èyí tí ó lógo. 11Ní ọjọ́ náà, Olúwa yóò na ọwọ́ rẹ̀ jáde nígbà kejì láti tún gba àwọn tí ó ṣẹ́kù àní àwọn tí a ṣẹ́kù nínú àwọn ènìyàn an rẹ̀ láti Asiria wá, láti ìsàlẹ̀ Ejibiti àti òkè Ejibiti, láti Kuṣi, láti Elamu láti Babiloni, láti Hamati àti láti àwọn erékùṣù inú Òkun. 12Òun yóò gbé àsíá sókè fún àwọn orílẹ̀-èdè,
yóò sì kó àwọn ìgbèkùn Israẹli jọ,
yóò kó gbogbo àwọn ènìyàn Juda tí a ti fọ́n káàkiri jọ,
láti igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ilẹ̀ ayé.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.